Leviticus 20:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
nígbà náà ni èmi gan-an yóo wá kẹ̀yìn sí olúwarẹ̀ ati gbogbo ìdílé rẹ̀, n óo sì yọ wọ́n kúrò lára àwọn eniyan wọn, ati òun, ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn rẹ̀, tí wọ́n jọ ń bọ oriṣa Moleki.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li emi o kọju si ọkunrin na, ati si idile rẹ̀, emi o si ke e kuro, ati gbogbo awọn ti o ṣe àgbere tọ̀ ọ lẹhin, lati ma ṣe àgbere tọ̀ Moleki lẹhin, lãrin awọn enia wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀ àti gbogbo ìdílé rẹ̀, èmi yóò sì ge wọn kúrò láàrin àwọn ènìyàn wọn: òun àti gbogbo àwọn tí ó dìjọ ṣe àgbérè tọ òrìṣà mólékì lẹ́yìn.