Leviticus 20:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Bí ẹnìkan bá ń lọ ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀, tabi àwọn oṣó, tí ó sì ń tọ̀ wọ́n lẹ́yìn, n óo kẹ̀yìn sí olúwarẹ̀, n óo sì yọ ọ́ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ọkàn ti o ba yipada tọ̀ awọn ti o ní ìmọ afọṣẹ, ati ajẹ́, lati ṣe àgbere tọ̀ wọn lẹhin, ani emi o kọju mi si ọkàn na, emi o si ke e kuro lãrin awọn enia rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá tọ àwọn abókúsọ̀rọ̀ àti àwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn lọ, tí ó sì ṣe àgbérè tọ̀ wọ́n lẹ́yìn: Èmi yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀; Èmi yóò sì gé e kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.