Leviticus 21:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kò sì gbọdọ̀ jáde kúrò ninu ibi mímọ́ náà, tabi kí ó sọ ibi mímọ́ Ọlọrun rẹ̀ di aláìmọ́, nítorí pé, òróró ìyàsímímọ́ Ọlọrun rẹ̀ wà lórí rẹ̀. Èmi ni OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni ki o máṣe jade kuro ninu ibi mimọ́, bẹ̃ni ki o máṣe bà ibi mimọ́ Ọlọrun rẹ̀ jẹ́, nitoripe adé oróro itasori Ọlọrun rẹ̀ mbẹ lori rẹ̀: Emi li OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kò gbọdọ̀ kúrò ní ibi mímọ́ Ọlọ́run tàbí kí ó sọ ọ́ di aláìmọ́ torí pé a ti fi ìfòróróyàn Ọlọ́run yà á sí mímọ́. Èmi ni OLÚWA.