Leviticus 21:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kò gbọdọ̀ fi opó ṣe aya tabi obinrin tí ó kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, tabi obinrin tí ó ti mọ ọkunrin, tabi aṣẹ́wó; kò gbọdọ̀ fẹ́ èyíkéyìí ninu wọn. Obinrin tí kò tíì mọ ọkunrin rí ni kí ó fẹ́ láàrin àwọn eniyan rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Opó, tabi obinrin ikọsilẹ, tabi ẹni-ibàjẹ́, tabi panṣaga, wọnyi ni on kò gbọdọ fẹ́: bikoṣe wundia ni ki o fẹ́ li aya lati inu awọn enia rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kò gbọdọ̀ fẹ́ opó tàbí ẹni tí a kọ̀ sílẹ̀ tàbí obìnrin tí ó ti fi àgbérè ba ara rẹ̀ jẹ́, ṣùgbọ́n kí ó fẹ́ obìnrin tí kò mọ ọkùnrin rí, láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.