Leviticus 21:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ní àbùkù kò gbọdọ̀ súnmọ́ ibi pẹpẹ láti rú ẹbọ, kì báà jẹ́ afọ́jú, tabi arọ, ẹni tí ijamba bá bà lójú jẹ́, tabi tí apá tabi ẹsẹ̀ rẹ̀ kan gùn ju ekeji lọ,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe gbogbo ọkunrin ti o ní àbuku, ki o máṣe sunmọtosi: ọkunrin afọju, tabi amukun, tabi arẹ́mu, tabi ohun kan ti o leke,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní àbùkù kò gbọdọ̀ sún mọ́ ibi ẹbọ náà. Kò gbọdọ̀ sí afọ́jú tàbí arọ, alábùkù ara tàbí àwọn tí ara wọn kò pé.