Leviticus 21:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n níláti jẹ́ mímọ́ fún Ọlọrun wọn, wọn kò sì gbọdọ̀ sọ orúkọ Ọlọrun wọn di aláìmọ́, nítorí pé àwọn ni wọ́n ń rú ẹbọ sísun sí OLUWA; èyí tíí ṣe oúnjẹ Ọlọrun wọn, nítorí náà wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki nwọn ki o si jasi mimọ́ fun Ọlọrun wọn, ki nwọn ki o má si ṣe bà orukọ Ọlọrun wọn jẹ́: nitoripe ẹbọ OLUWA ti a fi ina ṣe, ati àkara Ọlọrun wọn, ni nwọn fi nrubọ: nitorina ni ki nwọn ki o jẹ́ mimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún Ọlọ́run, kí wọ́n má baà sọ orúkọ Ọlọ́run wọn di àìmọ́, nítorí pé àwọn ni wọ́n ń fí iná sun ẹbọ sí OLÚWA wọn, ti ó jẹ oúnjẹ Ọlọ́run wọn. Nítorí náà wọn gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́.