Leviticus 21:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé alufaa jẹ́ ẹni mímọ́ fún Ọlọrun rẹ̀, kò gbọdọ̀ gbé aṣẹ́wó ní iyawo, tabi obinrin tí ó ti di aláìmọ́, tabi obinrin tí ó ti kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn kò gbọdọ fẹ́ aya ti iṣe àgbere, tabi ẹni ibàjẹ́; bẹ̃ni nwọn kò gbọdọ fẹ́ obinrin ti a ti ọdọ ọkọ rẹ̀ kọ̀silẹ: nitoripe mimọ́ li on fun Ọlọrun rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Àwọn àlùfáà kò gbọdọ̀ fẹ́ aṣẹ́wó tàbí obìnrin tí ó ti fi ọkùnrin ba ara rẹ̀ jẹ́ tàbí obìnrin tí ọkọ rẹ̀ ti kọ̀ sílẹ̀ nítorí pé àwọn àlùfáà jẹ́ mímọ́ sí Ọlọ́run wọn.