Leviticus 21:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ gbọdọ̀ ka alufaa sí ẹni mímọ́, nítorí òun ni ó ń rú ẹbọ ohun jíjẹ sí Ọlọrun yín. Ó níláti jẹ́ ẹni mímọ́ fun yín, nítorí pé èmi OLUWA tí mo yà yín sí mímọ́ jẹ́ mímọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ki ẹnyin ki o yà a simimọ́; nitoriti o nrubọ àkara Ọlọrun rẹ: yio jẹ́ mimọ́ si ọ: nitoripe mimọ́ li Emi OLUWA, ti o yà nyin simimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ènìyàn gbọdọ̀ máa kà wọ́n sí mímọ́, nítorí pé àwọn ni wọ́n ń rú ẹbọ oúnjẹ fún mi. Èmi ni OLÚWA, mo jẹ́ mímọ́, mo sì ya àwọn ènìyàn mi sí mímọ́.