Leviticus 22:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn bí ọmọbinrin alufaa kan bá jẹ́ opó, tabi tí ó ti kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ láì bímọ fún un, tí ó bá pada sí ilé baba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ó wà ní ọdọmọbinrin, ó lè jẹ ninu oúnjẹ baba rẹ̀; sibẹsibẹ àjèjì kankan kò gbọdọ̀ jẹ ninu rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi ọmọbinrin alufa na ba di opó, tabi ẹni-ikọsilẹ, ti kò si lí ọmọ, ti o si pada wá si ile baba rẹ̀, bi ìgba ewe rẹ̀, ki o ma jẹ ninu onjẹ baba rẹ̀: ṣugbọn alejò kan kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n bí ọmọbìnrin àlùfáà bá jẹ́ opó tàbí tí a ti kọ ọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n tí kò lọ́mọ tí ó sì padà sínú ilé bàbá rẹ̀ láti máa gbé bẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìgbà èwe rẹ̀, ó le jẹ oúnjẹ bàbá rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, ẹnikẹ́ni tí kò lẹtọ (láṣẹ) kò gbọdọ̀ jẹ èyíkéyí nínú oúnjẹ náà.