Leviticus 22:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
kí ó sọ fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati gbogbo àwọn eniyan Israẹli pé: “Nígbà tí ẹnìkan ninu àwọn eniyan Israẹli tabi àlejò tí ó wà láàrin wọn bá mú ohun ìrúbọ rẹ̀ wá, kì báà ṣe pé láti fi san ẹ̀jẹ́ kan ni, tabi gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àtinúwá, láti fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sọ fun Aaroni, ati fun awọn ọmọ rẹ̀, ati fun gbogbo awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ninu ile Israeli, tabi ninu awọn alejò ni Israeli, ti o ba fẹ́ ru ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ nitori ẹjẹ́ wọn gbogbo, ati nitori ẹbọ rẹ̀ atinuwá gbogbo, ti nwọn nfẹ́ ru si OLUWA fun ẹbọ sisun;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Sọ fún Árónì, àwọn ọmọ rẹ̀ àti fún gbogbo Ísírẹ́lì kí o sì wí fún wọn pé: ‘Bí ẹnikẹ́ni nínú yín yálà ọmọ Ísirẹ́lì ni tàbí àlejò tí ń gbé ní Ísírẹ́lì bá mú ẹ̀bùn wá fún ọrẹ ẹbọ sísun sí OLÚWA, yálà láti san ẹ̀jẹ́ tàbí ọrẹ àtinúwá.