Leviticus 22:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Sọ fún Aaroni ati àwọn ọmọkunrin rẹ̀ pé, kí wọ́n máa fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ lo àwọn nǹkan mímọ́ tí àwọn eniyan Israẹli yà sọ́tọ̀ fún mi, kí wọ́n má baà ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́. Èmi ni OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sọ fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, ki nwọn ki o yà ara wọn sọ̀tọ kuro ninu ohun mimọ́ awọn ọmọ Israeli, ki nwọn ki o má si ṣe bà orukọ mimọ́ mi jẹ́ ninu ohun wọnni, ti nwọn yàsimimọ́ fun mi: Emi li OLUWA,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Sọ fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ kí wọ́n fi ọ̀wọ̀ fún ọrẹ mímọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yà sọ́tọ̀ fún mi, kí wọ́n má baà ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́. Èmi ni OLÚWA.