Leviticus 22:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ rú ẹbọ alaafia sí OLUWA láti san ẹ̀jẹ́, tabi fún ọrẹ àtinúwá; kì báà jẹ́ láti inú agbo mààlúù tabi láti inú agbo aguntan ni yóo ti mú ẹran ìrúbọ yìí, ó níláti jẹ́ pípé, kò gbọdọ̀ ní àbùkù kan lára, kí ẹbọ náà lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ẹnikẹni ti o ba ru ẹbọ alafia si OLUWA, lati san ẹjẹ́, tabi ẹbọ ifẹ́-atinuwá ni malu tabi agutan, ki o pé ki o ba le dà; ki o máṣe sí abùku kan ninu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ẹnikẹ́ni bá mú ọrẹ àlàáfíà wá láti inú agbo màlúù tàbí ti àgùntàn, fún OLÚWA láti san ẹ̀jẹ́ pàtàkì tàbí fún ọrẹ àtinúwá. Ó gbọdọ̀ jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà láìní àbùkù.