Leviticus 22:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí wọ́n bá tẹ ẹran kan lọ́dàá, tabi bí kóró abẹ́ rẹ̀ bá fọ́, tabi tí abẹ́ rẹ̀ fàya, tabi tí wọ́n la abẹ́ rẹ̀, tabi tí wọ́n ṣá a lọ́gbẹ́ ní abẹ́, ẹ kò gbọdọ̀ mú un wá fún OLUWA, tabi kí ẹ fi rúbọ ninu gbogbo ilẹ̀ yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin kò gbọdọ mú eyiti kóro rẹ̀ fọ́, tabi ti a tẹ̀, tabi ti a ya, tabi ti a là, wá rubọ si OLUWA; ki ẹnyin máṣe e ni ilẹ nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ má ṣe fi ẹranko tí kóró ẹpọ̀n rẹ̀ fọ́ tàbí tí a tẹ̀, tàbí tí a yà tàbí tí a là rúbọ sí OLÚWA. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe èyí ní ilẹ̀ yín.