Leviticus 22:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Bí ẹ bá gba irú ẹran bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ àlejò, ẹ kò gbọdọ̀ fi rú ẹbọ ohun jíjẹ sí èmi Ọlọrun yín. Níwọ̀n ìgbà tí àbùkù bá ti wà lára wọn, OLUWA kò ní tẹ́wọ́gba irú wọn lọ́wọ́ yín, nítorí àbùkù náà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ ti ọwọ́ alejò rubọ àkara Ọlọrun nyin ninu gbogbo wọnyi; nitoripe ibàjẹ́ wọn mbẹ ninu wọn, abùku si mbẹ ninu wọn: nwọn ki yio dà fun nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ kò gbọdọ̀ gba irú ẹranko bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ àlejò kankan láti fi rúbọ gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ sí Ọlọ́run yín. A kò ní gbà wọ́n fún yín nítorí pé wọ́n ní àbùkù wọ́n sì díbàjẹ́.’ ”

Recommended Reading