Leviticus 22:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nígbà tí mààlúù, aguntan, tabi ewúrẹ́ bá bímọ, ẹ fi ọmọ náà sílẹ̀ pẹlu rẹ̀ fún ọjọ́ meje, láti ọjọ́ kẹjọ lọ ni ó tó lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún ẹbọ sísun sí OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati a ba bi akọmalu kan, tabi agutan kan, tabi ewurẹ kan, nigbana ni ki o gbé ijọ meje lọdọ iya rẹ̀; ati lati ijọ́ kẹjọ ati titi lọ on o di itẹwọgbà fun ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nígbà tí màlúù bá bímọ, tí àgùntàn bímọ, tí ewúrẹ́ sì bímọ, ọmọ náà gbọdọ̀ wà pẹ̀lú ìyá rẹ̀ fún ọjọ́ méje. Láti ọjọ́ kèjọ ni ó ti di ìtẹ́wọ́gbà fún ọrẹ àfinásun sí OLÚWA.