Leviticus 22:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí èyíkéyìí ninu arọmọdọmọ wọn bá súnmọ́ àwọn nǹkan mímọ́ wọ̀n-ọn-nì, tí àwọn eniyan Israẹli ti yà sí mímọ́ fún OLUWA; nígbà tí ó wà ní ipò àìmọ́, a óo mú ẹni náà kúrò lọ́dọ̀ mi. Èmi ni OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ninu gbogbo irú-ọmọ nyin ninu awọn iran nyin, ti o ba sunmọ ohun mimọ́, ti awọn ọmọ Israeli yàsimimọ́ fun OLUWA, ti o ní aimọ́ rẹ̀ lara rẹ̀, ọkàn na li a o ke kuro niwaju mi: Emi li OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Sọ fún wọn pé: ‘Fún àwọn ìran tí ń bọ̀. Bí ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ yín tí kò mọ́ bá wá síbi ọrẹ mímọ́ tí àwọn ara Ísírẹ́lì ti yà sọ́tọ̀ fún OLÚWA, kí ẹ yọ ẹni náà kúrò nínú iṣẹ́ àlùfáà ní iwájú mi. Èmi ni OLÚWA.