Leviticus 22:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ẹnikẹ́ni ninu ìran Aaroni tí ó bá ní àrùn ẹ̀tẹ̀, tabi tí ara rẹ̀ bá ń tú, kò gbọdọ̀ jẹ ninu àwọn ohun mímọ́ náà, títí tí yóo fi di mímọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan ohunkohun tí ó jẹ́ aláìmọ́, kì báà jẹ́ pé ó fara kan òkú ni, tabi pé ó fara kan ẹni tí nǹkan ọkunrin jáde lára rẹ̀,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnikẹni ninu irú-ọmọ Aaroni ti iṣe adẹtẹ, tabi ti o ní isun; ki o máṣe jẹ ninu ohun mimọ́, titi on o fi di mimọ́. Ati ẹnikẹni ti o farakàn ohun ti iṣe aimọ́, bi okú, tabi ọkunrin ti ohun-irú nti ara rẹ̀ jade;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Árónì bá ní àrùn ara tí ń ran ni, tàbí ìtújáde nínú ara. Ó lè má jẹ ọrẹ mímọ́ náà títí di ìgbà tí a ó fi wẹ̀ ẹ́ mọ́. Òun tún lè di aláìmọ́ bí ó bá fọwọ́ kan ohunkóhun tí òkú nǹkan bá sọ di àìmọ́ tàbí bí ó bá farakan ẹnikẹ́ni tí ó ní ìtújáde.