Leviticus 23:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ burẹdi tabi ọkà, kì báà jẹ́ ọkà yíyan tabi tútù títí di ọjọ́ yìí, tí ẹ óo fi mú ẹbọ Ọlọrun yín wá, ìlànà ni èyí yóo jẹ́ fún ìrandíran yín, ní gbogbo ilẹ̀ yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin kò si gbọdọ jẹ àkara, tabi ọkà yiyan, tabi ọkà tutù ninu ipẹ́, titi yio fi di ọjọ́ na gan ti ẹnyin mú ọrẹ-ẹbọ tọ̀ Ọlọrun nyin wá: ki o si jasi ìlana titilai ni iran-iran nyin ni ibujoko nyin gbogbo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ àkàrà kankan tàbí kí ẹ sun ọkà tuntun títí di ọjọ́ tí ẹ fi mú ọrẹ yín wá fún Ọlọ́run yín. Èyí ni ìlànà ayérayé fún ìran tí ń bọ̀, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé.