Leviticus 23:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ óo mú burẹdi meji tí wọ́n fi ìdámárùn-ún ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára ṣe wá fún ẹbọ fífì; àwọn àkàrà náà yóo ní ìwúkàrà ninu, ẹ óo mú wọn tọ OLUWA wá gẹ́gẹ́ bí àkọ́so oko yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ẹnyin ki o si mú lati inu ibugbé nyin wá, ìṣu-àkara fifì meji ti idamẹwa meji òṣuwọn: ki nwọn ki o jẹ́ ti iyẹfun daradara, ki a fi iwukàra yan wọn, akọ́so ni nwọn fun OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láti ibikíbi tí ẹ bá ń gbé, ẹ mú ìṣù àkàrà méjì tí a fi òṣùwọ̀n ìdáméjì nínú mẹ́wàá tí ẹ́fà (Èyí jẹ́ lítà mẹ́rin ààbọ̀) ti ìyẹ̀fun, tí a fi ìwúkàrà ṣe, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì àkọ́so sí OLÚWA.