Leviticus 23:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ óo mú ọ̀dọ́ aguntan meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbùkù lọ́wọ́, pẹlu ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan ati àgbò meji, nígbà tí ẹ bá ń kó àwọn ìṣù àkàrà meji náà bọ̀. Àwọn ni ẹ óo fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA; pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ, ati ẹbọ ohun mímu, ẹbọ tí a fi iná sun, olóòórùn dídùn, tí OLUWA gbádùn ni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pẹlu àkara na ki ẹnyin ki o si fi ọdọ-agutan meje ọlọdún kan alailabukù rubọ, ati ẹgbọrọ akọmalu kan, ati àgbo meji: ki nwọn ki o jẹ́ ẹbọ sisun si OLUWA, pẹlu ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn, ani ẹbọ ti a fi iná ṣe olõrùn didùn ni si OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ fi akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbùkù, ọmọ màlúù kan àti àgbò méjì kún àkàrà yìí: wọn yóò jẹ́ ọrẹ sísun sí OLÚWA.