Leviticus 23:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nígbà tí ẹ bá ń kórè oko yín, ẹ kò gbọdọ̀ kórè títí dé ààlà patapata. Lẹ́yìn tí ẹ bá ti kórè tán, ẹ kò gbọdọ̀ pada lọ tún kórè àwọn èso tí ẹ bá gbàgbé. Ẹ gbọdọ̀ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn talaka ati àwọn àlejò. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati ẹnyin ba nṣe ikore ilẹ nyin, iwọ kò gbọdọ ṣa ẹba oko rẹ li aṣatán, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ pèṣẹ́ ikore rẹ̀: ki iwọ ki o fi i silẹ fun awọn talaka, ati fun alejò: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Nígbà tí ẹ bá kórè ilẹ̀ yín ẹ má ṣe kórè dé ìkangun oko yín, tàbí kí ẹ padà gé èyí tí ó ṣẹ́kù sílẹ̀ nínú ìkórè yín. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn tálákà àti àwọn àlejò: Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín.’ ”