Leviticus 23:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọjọ́ mẹfa ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣugbọn ọjọ́ keje jẹ́ ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀, ati ọjọ́ ìpéjọ mímọ́. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà, ọjọ́ ìsinmi ni fún OLUWA ní gbogbo ibùgbé yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ijọ́ mẹfa ni ki a ṣe iṣẹ: ṣugbọn ni ijọ́ keje li ọjọ́ isimi, apejọ mimọ́; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ kan ninu rẹ̀: nitoripe ọjọ́-isimi OLUWA ni ninu ibujoko nyin gbogbo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Ọjọ́ mẹ́fà ni ẹ le fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìsinmi. Ọjọ́ ìpàdé àjọ mímọ́. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé. Ọjọ́ ìsinmi OLÚWA ni.