Leviticus 23:37 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Àwọn àjọ̀dún wọnyi ni OLUWA ti yà sọ́tọ̀; ẹ óo máa kéde wọn gẹ́gẹ́ bí àkókò ìpéjọpọ̀ mímọ́, láti máa rú ẹbọ tí a fi iná sun sí OLUWA, ẹbọ sísun, ati ẹbọ ohun jíjẹ; ati ẹbọ ohun mímu, olukuluku ní ọjọ́ tí a ti yàn fún wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wọnyi li ajọ OLUWA, ti ẹnyin o kedé lati jẹ́ apejọ mimọ́, lati ru ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA, ẹbọ sisun, ati ẹbọ ohunjijẹ, ẹbọ, ati ẹbọ ohunmimu, olukuluku wọn li ọjọ́ rẹ̀:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
(“ ‘Ìwònyí ni àwon àjọ̀dún tí OLÚWA ti yàn tí ẹ gbọdọ̀ kéde gẹ́gẹ́ bí i ìpàdé mímọ́ fún mímu àwọn ọrẹ tí a fi iná ṣe sí OLÚWA wá—ọrẹ sísun àti ọrẹ ọkà, ọrẹ ẹbọ àti ọrẹ ohun mímu, fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan: