Leviticus 23:40 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọjọ́ kinni, ẹ óo mú ninu àwọn èso igi tí ó bá dára, ati imọ̀ ọ̀pẹ, ati ẹ̀ka igi tí ó ní ewé dáradára, ati ẹ̀ka igi wilo etí odò, kí ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín fún ọjọ́ meje.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọjọ́ kini ki ẹnyin ki o si mú eso igi daradara, imọ̀-ọpẹ, ati ẹká igi ti o bò, ati ti igi wilo odò; ki ẹnyin ki o si ma yọ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun nyin ni ijọ́ meje.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kìn-ín-ní kí ẹ mú àṣàyàn èso láti orí igi, igi tẹ́ẹ́rẹ́ etídò, àti ẹ̀ka igi tó rúwé, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú OLÚWA Ọlọ́run yín fún ọjọ́ méje.