Leviticus 23:41 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọjọ́ meje láàrin ọdún kan ni ẹ óo máa fi ṣe àjọ̀dún fún OLUWA; Ìlànà títí lae ni èyí jẹ́ fún arọmọdọmọ yín. Ninu oṣù keje ọdún ni ẹ óo máa ṣe àjọ àjọ̀dún náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ẹnyin ki o si ma pa a mọ́ li ajọ fun OLUWA ni ijọ́ meje li ọdún: ìlana ni titilai ni iran-iran nyin: ki ẹnyin ki o ma ṣe e li oṣù keje.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ ṣe èyí ní àjọ̀dún sí OLÚWA fún ọjọ́ méje lọ́dọọdún. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀: Ẹ ṣe é ní oṣù keje.