Leviticus 24:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọkunrin kan wà tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Israẹli, ṣugbọn tí baba rẹ̀ jẹ́ ará Ijipti. Ní ọjọ́ kan, nígbà tí ó bá àwọn ọmọ Israẹli jáde, ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrin òun ati ọkunrin kan, tí ó jẹ́ ọmọ Israẹli, ní ibùdó.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ọmọkunrin obinrin Israeli kan, ti baba rẹ̀ ṣe ara Egipti, o jade lọ ninu awọn ọmọ Israeli: ọmọkunrin obinrin Israeli yi ati ọkunrin Israeli kan si jà ni ibudó.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọmọkùnrin kan wà tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì baba rẹ̀ sì jẹ́ ará Éjíbítì. Ó jáde lọ láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ìjà sì ṣẹlẹ̀ nínú àgọ́ láàrin òun àti ọmọ Ísírẹ́lì kan.