Leviticus 24:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọkunrin tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Israẹli yìí bá sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ OLUWA, bí ó ti ń búra ni ó ń ṣépè. Wọ́n bá mú un tọ Mose wá; orúkọ ìyá ọmọkunrin náà ni Ṣelomiti ọmọ Dibiri láti inú ẹ̀yà Dani.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Eyi ọmọkunrin obinrin Israeli yi, sọ̀rọ buburu si Orukọ nì, o si fi bú: nwọn si mú u tọ̀ Mose wá. Orukọ iya rẹ̀ ama jẹ Ṣelomiti, ọmọbinrin Dibri, ti ẹ̀ya Dani.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọmọkùnrin arábìnrin Ísírẹ́lì náà sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ OLÚWA pẹ̀lú èpè: Wọ́n sì mú-un tọ Mósè wá. (Orúkọ ìyá rẹ̀ ní Selomiti, ọmọbìnrin Débírì, ará Dánì).