Leviticus 24:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Mú ọkunrin tí ó ṣépè náà jáde kúrò láàrin ibùdó, kí gbogbo àwọn tí wọ́n gbọ́ nígbà tí ó ṣépè gbé ọwọ́ lé e lórí, kí gbogbo ìjọ eniyan sì sọ ọ́ ní òkúta pa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mú ẹniti o ṣe ifibu nì wá sẹhin ibudó; ki gbogbo awọn ti o si gbọ́ ọ ki o fi ọwọ́ wọn lé ori rẹ̀, ki gbogbo ijọ enia ki o le sọ ọ li okuta.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Mú asọ̀rọ̀òdì náà jáde wá sẹ́yìn àgọ́, kí gbogbo àwọn tí ó gbọ́ pé ó ṣépè gbé ọwọ́ wọn lórí ọkùnrin náà láti fi hàn pé ó jẹ̀bi. Lẹ́yìn náà ni kí gbogbo àpéjọpọ̀, sọ ọ́ ní òkúta pa.