Leviticus 24:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mose sọ ọ̀rọ̀ wọnyi fún àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. Wọ́n mú ọkunrin tí ó ṣépè náà jáde kúrò láàrin ibùdó, wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta pa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mose si sọ fun awọn ọmọ Israeli, pe ki nwọn ki o mú ẹniti o ṣe ifibu nì jade lọ sẹhin ibudó, ki nwọn ki o si sọ ọ li okuta pa. Awọn ọmọ Israeli si ṣe bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Mósè sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì mú asọ̀rọ̀òdì náà lọ sí ẹ̀yìn àgọ́: wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta pa. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe ohun tí OLÚWA pàṣẹ fún Mósè.