Leviticus 24:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ìrọ̀lẹ́, Aaroni yóo máa tan àtùpà náà kalẹ̀ níwájú aṣọ ìbòjú tí ó wà níwájú àpótí ẹ̀rí, wọn yóo máa wà ní títàn níwájú OLUWA títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji. Èyí yóo wà bí ìlànà, títí lae, fún arọmọdọmọ yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lẹhin ode aṣọ-ikele ẹrí, ninu agọ́ ajọ, ni ki Aaroni ki o tọju rẹ̀ lati aṣalẹ di owurọ̀ nigbagbogbo niwaju OLUWA: ìlana ni titilai ni iran-iran nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn aṣọ títa tibi àpótí ẹ̀rí tí ó wà ní inú àgọ́ ìpàdé, ni kí Árónì ti tan iná náà níwájú OLÚWA, láti ìrọ̀lẹ́ di àárọ̀ lójojúmọ́. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀.