Leviticus 24:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní gbogbo ọjọ́ ìsinmi, Aaroni yóo máa tò wọ́n kalẹ̀ níwájú OLUWA nígbà gbogbo, ní orúkọ àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bíi majẹmu títí lae.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọjọjọ́ isimi ni ki ẹ ma tun u tò niwaju OLUWA titi; gbigbà ni lọwọ awọn ọmọ Israeli nipa majẹmu titi aiye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Búrẹ́dì yìí ni kí ẹ gbé wá ṣíwájú OLÚWA nígbàkugbà, lọ́sẹ̀ọ̀sẹ̀, nítorí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú ayérayé.