Leviticus 24:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n ni àwọn burẹdi náà, ibi mímọ́ ni wọn yóo sì ti máa jẹ wọ́n, nítorí pé òun ni ó mọ́ jùlọ ninu ìpín wọn, ninu ọrẹ ẹbọ sísun sí OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki o si ma jẹ́ ti Aaroni ati ti awọn ọmọ rẹ; ki nwọn ki o si ma jẹ ẹ ni ibi mimọ́ kan: nitoripe mimọ́ julọ ni fun u ninu ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe, ìlana titilai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ló ni ín. Wọ́n gbọdọ̀ jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́ torí pé ó jẹ́ ipa tí ó mọ́ jùlọ ti ìpín wọn ojojúmọ́ nínú ọrẹ tí a fi iná ṣe sí OLÚWA.”