Leviticus 25:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ ya ọdún tí ó gbẹ̀yìn aadọta ọdún náà sí mímọ́, kí ẹ sì kéde ìdáǹdè jákèjádò gbogbo ilẹ̀ yín fún gbogbo àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀, yóo jẹ́ ọdún jubili fun yín. Ní ọdún náà, olukuluku yín yóo pada sórí ilẹ̀ rẹ̀ ati sinu ìdílé rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ẹnyin ki o si yà arãdọta ọdún simimọ́, ki ẹnyin ki o si kede idasilẹ ni ilẹ na fun gbogbo awọn ti ngbé inu rẹ̀: yio si ma jẹ́ jubeli fun nyin; ki ẹnyin ki o si pada olukuluku si ilẹ-iní rẹ̀, ki olukuluku nyin ki o si pada sinu idile rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ ya àádọ́ta ọdún náà sọ́tọ̀ kí ẹ sì kéde òmìnira fún gbogbo ẹni tí ń gbé ilẹ̀ náà. Yóò jẹ́ ọdún ìdásílẹ̀ fún yín. Kí olúkúlùkù padà sí ilẹ̀ ìní rẹ̀ àti sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹbí rẹ̀.