Leviticus 25:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọdún jubili ni ọdún tí ó gbẹ̀yìn aadọta ọdún yìí yóo jẹ́ fun yín. Ninu ọdún náà, ẹ kò gbọdọ̀ gbin ohunkohun, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ kórè ohun tí ó bá dá hù fúnra rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ ká àjàrà tí ó bá so ninu ọgbà àjàrà tí ẹ kò tọ́jú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọdún jubeli ni ki arãdọta ọdún ki o jasi fun nyin: ẹnyin kò gbọdọ gbìn, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ká ilalẹ-hù inu rẹ̀, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ká eso àjara rẹ̀ ti a kò rẹ-lọwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àádọ́ta ọdún ni yóò jẹ́ ọdún ìdásílẹ̀ fún yín. Ẹ má ṣe gbin ohunkóhun, ẹ kò sì gbọdọ̀ kórè ohun tí ó hù fúnrarẹ̀ tàbí kí ẹ kórè ọgbà àjàrà tí ẹ kò dá.