Leviticus 25:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Iye ọdún tí ó bá ti rékọjá lẹ́yìn ọdún jubili ni ẹ óo máa wò ra ilẹ̀ lọ́wọ́ aládùúgbò yín, iye ọdún tí ẹ bá fi lè gbin ohun ọ̀gbìn sórí ilẹ̀ kan kí ọdún jubili tó dé ni òun náà yóo máa wò láti tà á fun yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gẹgẹ bi iye ọdún lẹhin jubeli ni ki iwọ ki o rà lọwọ ẹnikeji rẹ, ati gẹgẹ bi iye ọdún ikore rẹ̀ ni ki o tà fun ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ẹ ra ilẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn yín ní gẹ́gẹ́ bí iye owó tí ó kù kí ọdún ìdásílẹ̀ pé, kí òun náà sì ta ilẹ̀ fún yín gẹ́gẹ́ bí iye ọdún rẹ̀ tó kù láti kórè.