Leviticus 25:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn bí kò bá ní agbára tó láti ra ilẹ̀ náà pada fúnra rẹ̀, ilẹ̀ náà yóo wà ní ọwọ́ ẹni tí ó rà á lọ́wọ́ rẹ̀ títí di ọdún jubili. Ní ọdún jubili, ẹni tí ó ra ilẹ̀ náà yóo dá a pada, ẹni tí ó ni ín yóo sì pada sórí ilẹ̀ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi o ba ṣepe on kò le san a pada fun u, njẹ ki ohun ti o tà na ki o gbé ọwọ́ ẹniti o rà a titi di ọdún jubeli: yio si bọ́ ni jubeli, on o si pada lọ si ilẹ-iní rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n bí kò bá rí ọ̀nà àti san án padà fún un. Ohun tí ó tà wà ní ìkáwọ́ ẹni tí ó ràá títí di ọdún ìdásílẹ̀. Kí ó dáa padà fún ẹni tí ó ni i ní ọdún ìdásílẹ̀, ẹni tí ó ni í tẹ́lẹ̀ lè tún padà gbà ohun ìní rẹ̀.