Leviticus 25:30 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ẹni náà kò bá ra ilé náà pada láàrin ọdún kan, ilé yóo di ti ẹni tí ó rà á títí lae ati ti arọmọdọmọ rẹ̀; kò ní jọ̀wọ́ rẹ̀ sílẹ̀ bí ọdún jubili tilẹ̀ dé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi a kò ba si rà a ni ìwọn ọdún kan gbako, njẹ ki ile na ki o di ti ẹniti o rà a titilai ni iran-iran rẹ̀: ki yio bọ́ ni jubeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n bí kò bá rà á padà láàrin ọdún náà ilé náà tí ó wà láàrin ìlú ni kí ó yọ̀ǹda pátapáta fún ẹni tí ó rà á, àti àwọn ìdílé rẹ̀. Kí wọ́n má da padà ní ọdún ìdásílẹ̀.