Leviticus 25:33 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn bí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Lefi kò bá lo ẹ̀tọ́ ìràpadà yìí, ẹni tí ó bá ra ilé náà lọ́wọ́ rẹ̀ ninu ìlú olódi, yóo jọ̀wọ́ ilé náà sílẹ̀ ní ọdún jubili, nítorí pé, àwọn ilé tí ó wà ní ìlú àwọn ọmọ Lefi jẹ́ ìní tiwọn láàrin àwọn eniyan Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi ẹnikan ba si rà lọwọ awọn ọmọ Lefi, njẹ ile ti a tà na, ni ilu iní rẹ̀, ki o bọ́ ni jubeli: nitoripe ile ilu awọn ọmọ Lefi ni ilẹ-iní wọn lãrin awọn ọmọ Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Torí náà ohun ìní àwọn ọmọ Léfì ni wọ́n rà padà, fún àpẹẹrẹ, èyí ni pé ilẹ̀ tí a bá tà ní ìlúkílú tí ó jẹ́ tiwọn, ó sì gbọdọ̀ di dídápadà ní ọdún ìdásílẹ̀, torí pé àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní ìlú àwọn Léfì ni ìní wọn láàrin àwọn ará Ísírẹ́lì