Leviticus 25:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn ọdún keje yóo jẹ́ ọdún ìsinmi tí ó ní ọ̀wọ̀ fún ilẹ̀ náà, ilẹ̀ náà yóo sinmi fún OLUWA, ẹ kò gbọdọ̀ gbin ohunkohun sinu oko yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ tọ́jú àjàrà yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ọdún keje ki o si jasi ìgba isimi fun ilẹ na, isimi fun OLUWA: iwọ kò gbọdọ gbìn oko rẹ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ rẹwọ ọgbà-àjara rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ní ọdún keje kí ilẹ̀ náà ní ìsinmi: ìsinmi fún OLÚWA. Ẹ má ṣe gbin èso ọgbà yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ rò wọ́n.