Leviticus 25:45 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ sì lè rà láàrin àwọn àlejò tí wọ́n wà láàrin yín ati àwọn ìdílé wọn tí wọ́n wà pẹlu yín, tí wọ́n bí ní ilẹ̀ yín, wọ́n lè di tiyín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pẹlupẹlu ninu awọn ọmọ alejò ti nṣe atipo pẹlu nyin, ninu wọn ni ki ẹnyin ki o rà, ati ninu awọn idile wọn ti mbẹ pẹlu nyin, ti nwọn bi ni ilẹ nyin: nwọn o si jẹ iní nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bákan náà, ẹ sì le è ra àwọn àlejò tí ń gbé láàrin yín, àti àwọn ìdílé wọn tí a bí sáàrin yín. Wọn yóò sì di ohun ìní yín.