Leviticus 25:46 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ lè fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn ọmọ yín nígbà tí ẹ bá kú, kí wọn lè jogún wọn títí lae. Wọ́n lè di ẹrú yín, ṣugbọn ẹ̀yin ọmọ Israẹli tí ẹ jẹ́ arakunrin ara yín, ẹ kò gbọdọ̀ mú ara yín sìn, ẹ kò sì gbọdọ̀ fi ọwọ́ líle mú ara yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin o si ma fi wọn jẹ ogún fun awọn ọmọ nyin lẹhin nyin, lati ní wọn ni iní; ẹnyin o si ma sìn wọn lailai: ṣugbọn ninu awọn arakunrin nyin awọn ọmọ Israeli, ẹnikan kò gbọdọ fi irorò sìn ẹnikeji rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ lè fi wọ́n sílẹ̀ bí ogún fún àwọn ọmọ yín; Wọ́n sìle sọ wọ́n di ẹrú títí láé. Ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ rorò mọ́ ọmọ Ísírẹ́lì kankan.