Leviticus 25:47 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Bí àlejò tí ó wà láàrin yín bá di ọlọ́rọ̀ tí arakunrin rẹ̀ tí ó jẹ́ aládùúgbò rẹ̀ sì di aláìní, tí ó sì ta ara rẹ̀ fún àlejò náà, tabi fún ọ̀kan ninu ìdílé àlejò yín,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati bi alejò tabi atipo kan ba di ọlọrọ̀ lọdọ rẹ, ati arakunrin rẹ kan leti ọdọ rẹ̀ ba di talakà, ti o ba si tà ara rẹ̀ fun alejò tabi atipo na leti ọdọ rẹ, tabi fun ibatan idile alejò na:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Bí àlejò kan láàrin yín tàbí ẹni tí ń gbé àárin yín fún ìgbà díẹ̀ bá lọ́rọ̀ tí ọmọ Ísírẹ́lì sì talákà débi pé ó ta ara rẹ̀ lẹ́rú fún àlejò tàbí ìdílé àlejò náà.