Leviticus 25:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìsinmi ilẹ̀ yìí ni yóo mú kí oúnjẹ wà fun yín: ati ẹ̀yin alára, tọkunrin tobinrin yín, ati àwọn ẹrú, ati àwọn alágbàṣe yín, ati àwọn àlejò tí wọ́n ń ba yín gbé,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọdún isimi ilẹ na yio si ma ṣe ohunjijẹ fun nyin; fun iwọ, ati fun iranṣẹ rẹ ọkunrin, ati fun iranṣẹ rẹ obinrin, ati fun alagbaṣe rẹ, ati fun alejò rẹ ti nṣe atipo lọdọ rẹ;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ohunkóhun tí ilẹ̀ náà bá mú jáde ní ọdún ìsinmi ni yóò jẹ́ oúnjẹ fún yín àní fún ẹ̀yin tìkálárayín, àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin yín, àwọn alágbàṣe àti àwọn tí ń gbé pẹ̀lú yín fún ìgbàdíẹ̀.