Leviticus 26:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe oriṣa-koriṣa kan fún ara yín, tabi kí ẹ gbé ère gbígbẹ́ kalẹ̀, tabi kí ẹ ri ọ̀wọ̀n òkúta gbígbẹ́ mọ́lẹ̀, kí ẹ sì máa bọ wọ́n, ní gbogbo ilẹ̀ yín, nítorí pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
ẸNYIN kò gbọdọ yá oriṣa, bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ gbé ere tabi ọwọ̀n kan dide naró fun ara nyin, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ gbé ere okuta gbigbẹ kalẹ ni ilẹ nyin, lati tẹriba fun u: nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ mọ ère òrìsà, tàbí kí ẹ̀yin gbe ère kalẹ̀ tàbí kí ẹ̀yin gbẹ́ ère òkúta: kí ẹ̀yin má sì gbẹ́ òkúta tí ẹ̀yin yóò gbé kalẹ̀ láti sìn. Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín.