Leviticus 26:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ óo jẹ àwọn nǹkan oko tí ẹ kó sí inú abà fún ọjọ́ pípẹ́, ẹ óo sì máa ru ìyókù wọn dànù kí ẹ lè rí ààyè kó tuntun sí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin o si ma jẹ ohun isigbẹ, ẹnyin o si ma kó ohun ẹgbẹ jade nitori ohun titun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn èrè oko yín yóò pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin ó máa jẹ èrè ọdún tí ó kọjá, ẹ̀yin ó sì kó wọn jáde: kí ẹ̀yin lè rí àyè kó túntún sí.