Leviticus 26:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo fi ogun ko yín, tí yóo gbẹ̀san nítorí majẹmu mi. Bí ẹ bá sì kó ara yín jọ sinu àwọn ìlú olódi yín, n óo rán àjàkálẹ̀ àrùn sí ààrin yín, n óo sì fi yín lé àwọn ọ̀tá yín lọ́wọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si mú idà wá sori nyin, ti yio gbà ẹsan majẹmu mi; a o si kó nyin jọ pọ̀ ninu ilu nyin, emi o rán ajakalẹ-àrun sãrin nyin; a o si fi nyin lé ọtá lọwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò mú ogun wá bá yín nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín láti fi gbẹ̀san májẹ̀mú mi tí ẹ kò pa mọ́. Bí ẹ ba sálọ sí ìlú yín fún ààbò: Èmi yóò rán àjàkálẹ̀-àrùn sí ààrín in yín: Àwọn ọ̀ta yín, yóò sì ṣẹ́gun yín.