Leviticus 26:34 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ẹ bá wà ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín, ilẹ̀ ti ẹ̀yin pàápàá yóo wá ní ìsinmi, níwọ̀n ìgbà tí ó bá wà ní ahoro, ilẹ̀ yín yóo gbádùn ìsinmi rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni ilẹ na yio ní isimi rẹ̀, ni gbogbo ọjọ́ idahoro rẹ̀, ẹnyin o si wà ni ilẹ awọn ọtá nyin; nigbana ni ilẹ yio simi, ti yio si ní isimi rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ilẹ̀ náà yóò ní ìsinmi (tí kò ni lákòókò ìsinmi rẹ̀) fún gbogbo ìgbà tí ẹ fi wà ní ilẹ̀ àjèjì tí ẹ kò fi lò ó. Ìlẹ̀ náà yóò sinmi láti fi dípò ọdún tí ẹ kọ̀ láti fún un.