Leviticus 26:36 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ìwọ̀nba àwọn tí wọ́n bá kù, n óo da jìnnìjìnnì bo ọkàn wọn ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín, tóbẹ́ẹ̀ tí ìró ewé tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lásán yóo máa lé wọn sá; wọn yóo sì máa sá àsá-dojúbolẹ̀ bí ẹni pé ogun ní ń lé wọn. Wọn yóo máa ṣubú nígbà tí ẹnikẹ́ni kò lé wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati lara awọn ti o kù lãye ninu nyin, li emi o rán ijàiya si ọkàn wọn ni ilẹ awọn ọtá wọn: iró mimì ewé yio si ma lé wọn; nwọn o si sá, bi ẹni sá fun idà; nwọn o si ma ṣubu nigbati ẹnikan kò lepa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Èmi yóò jẹ́ kí ó burú fún àwọn tí ó wà ní ilẹ̀ ìgbékùn débi pé ìró ewé tí ń mì lásán yóò máa lé wọn sá. Ẹ ó máa sáré bí ìgbà tí wọ́n ń lé yín lójú ogun. Ẹ ó sì subú láìsí ọ̀ta láyìíká yín