Leviticus 26:43 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn wọn yóo jáde kúrò ninu ilẹ̀ náà, ilẹ̀ náà yóo sì ní ìsinmi nígbà ti ó bá wà ní ahoro, nígbà tí wọn kò bá sí níbẹ̀. Wọ́n gbọdọ̀ gba ìjẹníyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí pé, wọ́n kẹ́gàn ìdájọ́ mi, wọ́n sì kórìíra ìlànà mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si fi ilẹ na silẹ, on o si ní isimi rẹ̀, nigbati o ba di ahoro li aisí wọn; nwọn o si gbà ibawi ẹ̀ṣẹ wọn: nitoripe, ani nitoripe nwọn gàn idajọ mi, ati ọkàn wọn korira ìlana mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ènìyàn náà yóò sì fi ilẹ̀ náà sílẹ̀, yóò sì ní ìsinmi rẹ̀ nígbà tí ó bá wà lófò láìsí wọn níbẹ̀. Wọn yóò sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn torí pé wọ́n kọ àwọn òfin mi. Wọ́n sì kórira àwọn àṣẹ mi.