Leviticus 26:44 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Sibẹsibẹ nígbà tí wọ́n bá wà ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn, n kò ní ṣàì náání wọn; bẹ́ẹ̀ ni n kò ní kórìíra wọn débi pé kí n pa wọ́n run patapata, kí n sì yẹ majẹmu mi pẹlu wọn, nítorí èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn sibẹ̀ ninu gbogbo eyina, nigbati nwọn ba wà ni ilẹ awọn ọtá wọn, emi ki yio tà wọn nù, bẹ̃li emi ki yio korira wọn, lati run wọn patapata, ati lati dà majẹmu mi pẹlu wọn: nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun wọn:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, nígbà tí wọ́n bá wà nílé àwọn ọ̀ta wọn, èmi kì yóò ta wọ́n nù, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò kóríra wọn pátapáta: èyi tí ó lè mú mi dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn. Èmi ni Ọlọ́run wọn